Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tó ń wá ibi ìsádi ni àwọn tó sá fún ogun, inúnibíni tàbí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ nílùú wọn, tí wọ́n sì sá lọ sílùú míì tàbí orílẹ̀-èdè míì fún ààbò. Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR) sọ pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ẹnì kan nínú ẹni mẹ́tàléláàádọ́fà [113] ló ń wá ibi ìsádi kárí ayé.