Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jésù ò sọ bóyá òótọ́ lẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ìránṣẹ́ náà. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí fẹ̀sùn kàn nínú Lúùkù 16:1 ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn kan fẹ́ bà á lórúkọ jẹ́. Àmọ́, ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ ni ohun tí ìránṣẹ́ náà ṣe, kì í ṣe ohun tó fà á tí wọ́n fi fẹ́ lé e lẹ́nu iṣẹ́.