Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìgbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12] la gbúròó Jósẹ́fù kẹ́yìn. Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀ nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn nígbà tó sọ omi di ọtí wáìnì, a ò sì tún gbúròó rẹ̀ lẹ́yìn náà. Nígbà tí Jésù wà lórí òpó igi oró, ó ní kí àpọ́sítélì Jòhánù máa tọ́jú Màríà. Kò sì dájú pé Jésù máa ṣe bẹ́ẹ̀ ká sọ pé Jósẹ́fù ṣì wà láàyè.—Jòh. 19:26, 27.