Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kristẹni kan lè pinnu pé òun nílò ìbọn tóun á fi máa ṣọdẹ tàbí tóun lè fi dáàbò bo ara òun lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, láwọn ìgbà tí kò bá lo ìbọn náà, ó yẹ kó yọ ọta kúrò nínú rẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ tú ìbọn náà palẹ̀, kó sì tọ́jú rẹ̀ síbi tọ́wọ́ àwọn míì kò ti ní tó o. Láwọn ìlú tí ìjọba kò ti fọwọ́ sí i pé kéèyàn ní ìbọn tàbí tí wọ́n ṣòfin nípa bí wọ́n á ṣe lò ó, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ pa òfin ìjọba mọ́.—Róòmù 13:1.