Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ̀ pé àfikún làwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 7:53 sí 8:11, àti pé kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn kan máa ń tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì yìí, wọ́n á sì sọ pé ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀ rí ló lè sọ pé ẹnì kan jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà. Àmọ́ òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ọkùnrin kan tí ó sùn ti obìnrin kan tí ó jẹ́ ti ẹnì kan, nígbà náà kí àwọn méjèèjì kú pa pọ̀.”—Diu. 22:22.