Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn awalẹ̀pìtàn rí ọkà rẹpẹtẹ lábẹ́ àwókù ìlú Jẹ́ríkò, tó fi hàn pé wọn ò sàga ti ìlú náà fún àkókò gígùn. Ọlọ́run ti pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó àwọn nǹkan tó wà nílùú Jẹ́ríkò títí kan oúnjẹ. Torí náà, àsìkò tó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kógun wá gan-an ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé àsìkò ìkórè ló bọ́ sí, oúnjẹ sì pọ̀ láyìíká tí wọ́n lè jẹ.—Jóṣ. 5:10-12.