Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn fún ọdún 2019 sọ ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ bí àwọn nǹkan burúkú bá tiẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé tàbí tá a bá kojú ìṣòro. A máa jíròrò kókó mẹ́ta yìí àti ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì jẹ́ kí àníyàn bò wá mọ́lẹ̀. Ronú jinlẹ̀ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yìí. Há a sórí tó bá ṣeé ṣe fún ẹ. Á fún ẹ lókun láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tó lè dìde lọ́jọ́ iwájú.