Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbólóhùn náà, “Má fòyà” fara hàn nínú Aísáyà 41:10, 13 àti 14. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì làwọn ẹsẹ yẹn lo “èmi” láti tọ́ka sí Jèhófà. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè tẹ kókó pàtàkì kan mọ́ wa lọ́kàn, ìyẹn ni pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé òun, ọkàn wa máa balẹ̀, a ò sì ní bẹ̀rù.