Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ṣé a máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àbí àá jẹ́ kí Sátánì tàn wá débi tá a fi máa kẹ̀yìn sí Jèhófà? Kì í ṣe bí ìdẹwò Sátánì ṣe lágbára tó ló máa pinnu, bí kò ṣe bá a ṣe dáàbò bo ọkàn wa tó. Kí ni ọ̀rọ̀ náà, ọkàn túmọ̀ sí bó ṣe wà nínú Bíbélì? Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì máa ń lò láti sọ ọkàn wa dìbàjẹ́? Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.