Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè ṣàyẹ̀wò ohun tá à ń rò, bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti ohun tá à ń ṣe, ká sì pinnu bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ohun tí Jèhófà fi jíǹkí wa yìí ni Bíbélì pè ní ẹ̀rí ọkàn. (Róòmù 2:15; 9:1) Ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ máa ń mú ká ronú lórí ìlànà Jèhófà, bó ṣe wà nínú Bíbélì, ká sì lò ó láti fi mọ̀ bóyá èrò wa, ọ̀rọ̀ wa tàbí ìṣe wa dára tàbí kò dára.