Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Láìpẹ́, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tàbí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ètò ráńpẹ́ tí Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn túbọ̀ mú kó ṣe kedere pé Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó nígboyà, ó sì nífẹ̀ẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò báwa náà ṣe lè gbé àwọn ànímọ́ yìí yọ ká sì fìwà jọ Jésù.