Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ní ìrọ̀lẹ́ Friday April 19, 2019, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó jẹ́ ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́dún. Kí nìdí tá a fi ń lọ sípàdé yìí? Kò sí àní-àní pé torí ká lè múnú Jèhófà dùn ni. Bá a ṣe ń lọ sí Ìrántí Ikú Kristi àtàwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ń sọ nǹkan kan nípa wa. Kí nìyẹn? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.