Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́? Kí nìdí tí Jèhófà fi mọyì pé káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa hùwà tó tọ́ nígbà gbogbo? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa jẹ́ olóòótọ́? A máa rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. Bákan náà, á jẹ́ ká rí bá a ṣe lè túbọ̀ pinnu pé àá máa hùwà tó tọ́ nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.