Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ọkàn tútù. Àwọn ọlọ́kàn tútù sábà máa ń jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, wọn kì í sì í fara ya kódà tí wọ́n bá múnú bí wọn. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í gbéra ga, wọ́n sì gbà pé àwọn míì sàn ju àwọn lọ. Tí Bíbélì bá sọ pé Jèhófà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ó máa ń fìfẹ́ bá àwọn tó rẹlẹ̀ sí i lò, ó sì máa ń ṣàánú wọn.