Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run nígbà tí Jésù wà láyé. Ìgbà kan wà nínú ìgbà mẹ́ta yẹn tí Jèhófà ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fetí sí Ọmọ òun. Lónìí, Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Bákan náà, ó ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń fetí sí Jèhófà àti Jésù.