Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fún àwọn ẹ̀mí èṣù, ó sì sọ àkóbá tí wọ́n máa ń fà. Báwo làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe máa ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? Kí la lè ṣe tá ò fi ní kó sí wọn lọ́wọ́? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa kó sí pańpẹ́ wọn.