Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ìbẹ́mìílò ni àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tó jẹ mọ́ tàwọn ẹ̀mí èṣù. Lára ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ pé ohun kan wà lára èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn téèyàn bá kú tàbí pé ó ṣeé ṣe láti bá òkú sọ̀rọ̀ bóyá nípasẹ̀ ẹnì kan tó jẹ́ abẹ́mìílò. Yàtọ̀ síyẹn, ìbẹ́mìílò ni téèyàn bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àjẹ́ tàbí iṣẹ́ wíwò. Bá a ṣe lò ó nínú àpilẹ̀kọ yìí, idán pípa wà lára iṣẹ́ awo àti lílo agbára abàmì. Ohun kan náà ni kéèyàn máa sà sí ẹlòmíì, kó fi èèdì dì í tàbí kó tú u sílẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe ìbẹ́mìílò téèyàn bá kàn ń fi ọwọ́ ṣe awúrúju kó lè pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín.