Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Àwọn alàgbà kò láṣẹ láti ṣòfin nípa irú eré ìnàjú tó yẹ káwọn ará máa wò tàbí lọ́wọ́ sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ láti pinnu ìwé tó máa kà, orin tó máa tẹ́tí sí, fíìmù tó máa wò àtàwọn eré ìnàjú míì tó máa gbádùn. Àwọn olórí ìdílé tó gbọ́n máa ń rí i dájú pé eré ìnàjú tí ìdílé wọn ń gbádùn bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu.—Wo àpilẹ̀kọ yìí lórí jw.org®, “Ṣé Ó Láwọn Fíìmù, Ìwé Tàbí Orin Tẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ò Gbọ́dọ̀ Gbádùn?” lábẹ́ abala NÍPA WA > ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ.