Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ni tí ẹni tó dàgbà bá ń bá ọmọdé lò láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Lára irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni pé kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọdé ní tààràtà tàbí láti ihò ìdí. Ohun kan náà ni tó bá ki ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ sẹ́nu ọmọ náà, tó bá ní kó máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ òun tàbí tí òun náà ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀, ọmú rẹ̀, ìdí rẹ̀ tàbí tó ń hùwà èyíkéyìí tá a lè pè ní ìṣekúṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn ọmọdé tí wọ́n máa ń bá ṣèṣekúṣe, síbẹ̀ wọ́n máa ń bá àwọn ọmọdékùnrin náà ṣèṣekúṣe. Òótọ́ ni pé ọkùnrin ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, síbẹ̀ àwọn obìnrin náà máa ń hùwà burúkú yìí.