Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Lédè Swahili, “Kitawala” túmọ̀ sí “jọba lé, darí tàbí ṣàkóso.” Ìdí tí wọ́n fi dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ gba òmìnira kúrò lábẹ́ ìjọba Belgium. Àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí máa ń gba ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń kà á, wọ́n ń pín in kiri, wọ́n sì ń yí ohun tó wà nínú rẹ̀ pa dà kí wọ́n lè fi ti ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n fi ń kọ́ni lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń lò ó láti gbé ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìwà ìṣekúṣe wọn lárugẹ.