Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ síwájú, ká sì máa sunwọ̀n sí i nínú ìjọsìn wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Fílípì, ó sọ àwọn nǹkan táá jẹ́ ká lè fara dà á nínú eré ìje ìyè tá à ń sá. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò.