Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀWÒRÁN: Lásìkò tí ìjọ ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Joe dáwọ́ iṣẹ́ tó ń ṣe dúró, ó sì ń bá arákùnrin kan àti ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ohun tó ṣe yẹn bí Arákùnrin Mike tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ nínú. Mike ronú pé, ‘Kì í ṣe ẹjọ́ ló yẹ kí Joe máa tò báyìí, iṣẹ́ ló yẹ kó máa ṣe.’ Ẹ̀yìn ìyẹn ni Mike rí Joe tó ń ran arábìnrin àgbàlagbà kan lọ́wọ́. Ohun tí Mike rí yìí mú kó rí i pé àwọn ànímọ́ rere tí Joe ní ló yẹ kóun gbájú mọ́.