Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nígbà míì, ó lè ṣẹlẹ̀ pé káwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ tàbí kí ètò Ọlọ́run fún wọn níṣẹ́ míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n máa ń kojú àtohun táá jẹ́ kó rọrùn fún wọn nínú ipò tuntun tí wọ́n bára wọn. Àá tún sọ báwọn míì ṣe lè fún wọn níṣìírí kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Bákan náà, a máa jíròrò àwọn ìlànà mélòó kan tó lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ tí nǹkan bá yí pa dà fún wa.