Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn ọmọ ogun mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn gbé apata dání torí ó máa dáàbò bò wọ́n. Bí apata yìí ni ìgbàgbọ́ wa náà rí. Bó ti ṣe pàtàkì pé kí ọmọ ogun kan bójú tó apata rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì ká rí i pé ìgbàgbọ́ wa dúró sán-ún. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ kí “apata ńlá ti ìgbàgbọ́” wa dúró sán-ún.