Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà ṣe ètò àkànṣe kan fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ kí wọ́n lè gbádùn òmìnira. Ètò yẹn ni Bíbélì pè ní Júbílì. Òótọ́ ni pé àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, síbẹ̀ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ètò Júbílì náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Júbílì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe láyé àtijọ́ ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun kan tí Jèhófà ṣe fún wa àti bó ṣe ṣe wá láǹfààní.