Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2020 rọ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà pé ká máa sọ àwọn èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn.” Gbogbo wa pátá ni àṣẹ tí Jésù pa yìí kàn. Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tí òtítọ́ á fi dọ́kàn wọn tí wọ́n á sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bákan náà, a máa jíròrò ohun táá jẹ́ ká mọ̀ bóyá ká dá ìkẹ́kọ̀ọ́ kan dúró tàbí ká ṣì máa bá a lọ.