Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Onírúurú ìṣòro ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Lásìkò tí gbogbo nǹkan nira fún un yẹn, orísun ìtùnú làwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ jẹ́ fún un. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ànímọ́ mẹ́ta tó jẹ́ káwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ orísun ìtùnú fún un. A sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa báwa náà ṣe lè jẹ́ orísun ìtùnú bíi tiwọn.