Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ẹni àmì òróró: Ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà fi ń yan ẹnì kan láti bá Jésù jọba lọ́run. Ẹ̀mí yìí ni Jèhófà fi máa ṣe “àmì ìdánilójú ogún” tí ẹni náà ń retí tàbí kó fi ṣèlérí fún un pé ọ̀run ni yóò ti gba èrè rẹ̀. (Éfé. 1:13, 14) Àwọn Kristẹni tí Jèhófà fẹ̀mí yàn yìí ló lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ “ń jẹ́rìí” tàbí pé ó ń mú kó ṣe kedere sáwọn pé ọ̀run làwọn ti máa gba èrè àwọn.—Róòmù 8:16.