Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c ÀWÒRÁN: Níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, wọ́n pinnu pé kí arákùnrin àgbàlagbà tó ti ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ dá alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa bójú tó iṣẹ́ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin àgbàlagbà náà gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an, tinútinú ló fi fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà yòókù ṣe. Ó dá arákùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́, ó fún un láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn án lọ́wọ́, ó sì gbóríyìn fún un tọkàntọkàn.