Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jésù sọ pé ìfẹ́ làwọn èèyàn fi máa dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, àá sapá láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn, a ò ní máa ṣojúsàájú, àá sì máa ṣe aájò àlejò. Ohun tá a sọ yìí lè dùn ún sọ, àmọ́ ó lè má fìgbà gbogbo rọrùn. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan pàtó táá jẹ́ ká túbọ̀ máa fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn látọkàn wá.