Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ojú wo lo fi ń wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ, ṣé ìyẹn sì mú kó o tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ojú tí Jésù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn tí wọ́n wàásù fún àti bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Àá rídìí tó fi yẹ ká mọ ohun táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa gbà gbọ́ àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ká sì tún ní in lọ́kàn pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn.