Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Torí pé aláìpé ni wá, a sábà máa ń ní èrò òdì nípa àwọn míì, a sì máa ń fura sí wọn. Àmọ́ Jèhófà “ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.” (1 Sám. 16:7) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ ran Jónà, Èlíjà, Hágárì àti Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Bákan náà, a máa rí bá a ṣe lè fara wé Jèhófà nínú bá a ṣe ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lò.