Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn àpọ́sítélì lo ọdún mélòó kan pẹ̀lú Jésù, wọ́n jọ sọ̀rọ̀, wọ́n jọ ṣiṣẹ́, ìyẹn sì mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ ara wọn. Jésù fẹ́ káwa náà di ọ̀rẹ́ òun, àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti dọ̀rẹ́ Jésù tí kò sì rí bẹ́ẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro láti di ọ̀rẹ́ Jésù, àá sì sọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ rẹ̀ kí okùn ọ̀rẹ́ wa má sì já.