Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn kan tí wọ́n ti ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún ti ń rẹ̀wẹ̀sì báyìí, kódà àwọn míì ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Kí ló fà á? Báwo lọ̀rọ̀ wọn ṣe rí lára Jèhófà? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn olóòótọ́ kan lọ́wọ́ láyé àtijọ́ nígbà tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, àá sì rí ohun tíyẹn kọ́ wa.