Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jèhófà fẹ́ káwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ pa dà sọ́dọ̀ òun. Ìdí nìyẹn tó fi ń rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi.” Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Bẹ́ẹ̀ ni! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.