Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn ìgbà kan wà tá a sọ nínú àwọn ìwé wa pé kò tọ̀nà ká máa sọ pé ká dá orúkọ Jèhófà láre torí pé kò sẹ́ni tó nàka àbùkù sí i pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ orúkọ náà. Àmọ́, a ní òye tuntun nípa èyí níbi ìpàdé ọdọọdún tó wáyé lọ́dún 2017. Alága ìpàdé náà sọ pé: ‘Kókó náà ni pé, kò sóhun tó burú nínú kéèyàn gbàdúrà fún ìdáláre orúkọ Jèhófà torí pé Jèhófà ní láti jẹ́ káráyé mọ̀ pé èké lẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.’—Wo ètò ti January 2018 lórí ìkànnì jw.org®. Wo abẹ́ OHUN TÁ A NÍ > JW BROADCASTING®.