Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Agbéraga èèyàn máa ń ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì máa ń fojú pa àwọn míì rẹ́. Torí náà, onímọtara-ẹni-nìkan ni. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká gba tàwọn míì rò. Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í gbéra ga, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jọra ẹ̀ lójú.