Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Sátánì tó jẹ́ baba irọ́ ló ń darí ayé tá à ń gbé yìí. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń gba ìsapá ká tó lè máa rìn nínú òtítọ́. Bó sì ṣe rí nìyẹn fáwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Kí Jèhófà lè ran àwọn àtàwa lọ́wọ́, ó mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti kọ lẹ́tà mẹ́ta kan. Nínú àwọn lẹ́tà yẹn, a máa rí àwọn nǹkan tó lè mú kó nira fún wa láti máa rìn nínú òtítọ́ àtàwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè borí wọn.