Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó lè má rọrùn fún wa láti mú sùúrù bá a ṣe ń dúró dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn sì lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Kí la rí kọ́ lára Ábúráhámù táá jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a máa ní sùúrù títí dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ láìka àwọn ìṣòro tá à ń kojú sí? Àpẹẹrẹ tó dáa wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní sì fi lélẹ̀?