Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ẹni tó nírẹ̀lẹ̀ máa ń ṣàánú àwọn èèyàn ó sì máa ń gba tiwọn rò. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan la máa kọ́ látinú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní. A tún máa jíròrò ohun tá a lè kọ́ lára Ọba Sọ́ọ̀lù, wòlíì Dáníẹ́lì àti Jésù tó bá kan kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹni.