Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: ‘Ibi ẹsẹ̀ olùkọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn sábà máa ń jókòó sí kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ káwọn náà lè di olùkọ́ lọ́jọ́ iwájú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kò fàyè gba àwọn obìnrin láti jókòó síbi ẹsẹ̀ olùkọ́, ohun tí Màríà ṣe lọ́jọ́ yẹn fi hàn pé ó mọyì ẹ̀kọ́ Jésù gan-an dípò kó máa ṣe kùrùkẹrẹ nídìí oúnjẹ. Ohun tó ṣe yìí máa ya àwọn ọkùnrin Júù lẹ́nu, á sì bí wọn nínú.’