Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ṣé ẹ̀ ń jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdíwọ́ lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe ń lo àkókò àlàáfíà tẹ́ ẹ ní báyìí? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè fara wé Ọba Ásà ti ilẹ̀ Júdà àtàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n fi ọgbọ́n lo àkókò tí kò sí wàhálà láti jọ́sìn Jèhófà.