Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọjọ́ pàtàkì ni March 27, 2021 jẹ́ fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Alẹ́ ọjọ́ yẹn la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn tí Jésù pè ní “àgùntàn mìíràn” ló máa pọ̀ jù lára àwọn tó máa kóra jọ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Òye wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nípa àgùntàn mìíràn lọ́dún 1935? Ìrètí wo làwọn àgùntàn mìíràn ń fojú sọ́nà fún lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá? Bákan náà, báwo ni wọ́n ṣe ń yin Jèhófà àti Kristi nígbà Ìrántí Ikú Kristi bí wọn ò tiẹ̀ jẹ nínú búrẹ́dì tí wọn ò sì mu nínú wáìnì náà?