Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Àwọn àgùntàn mìíràn ni àwọn tó ń tẹ̀ lé Kristi, wọ́n sì nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Àtìgbà tí ọjọ́ ìkẹyìn ti bẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà ti ń kó lára wọn jọ. Apá kan lára àwọn àgùntàn mìíràn ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn. Àwọn yìí máa wà láàyè nígbà tí Jésù bá ṣèdájọ́ aráyé nígbà ìpọ́njú ńlá, wọ́n á sì la ìpọ́njú ńlá náà já.