Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àpọ́sítélì Jòhánù ni “ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́.” (Jòh. 21:7) Èyí fi hàn pé nígbà tí Jòhánù wà pẹ̀lú Jésù, ó láwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kó kọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìfẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jòhánù kọ, àá sì kẹ́kọ̀ọ́ lára òun fúnra ẹ̀.