Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Jésù sọ pé ìfẹ́ tí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní síra wọn làwọn èèyàn fi máa dá wọn mọ̀. Ó dájú pé gbogbo wa là ń sapá láti máa fìfẹ́ hàn síra wa lẹ́nì kìíní kejì. Síbẹ̀, a lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún wọn, ìyẹn irú ìfẹ́ táwọn ọmọ ìyá kan náà máa ń ní síra wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀.