Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú Bíbélì, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa lókun, òun sì máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, tó sì lè mú ká pàdánù ojúure ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tá a fi nílò ààbò Jèhófà? Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá? Kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè dáàbò bò wá?