Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c ÀWÒRÁN: (látòkèdélẹ̀): Tọkọtaya kan ń wàásù láwọn ibi tó ti ṣòro láti bá àwọn èèyàn nílé. Ẹni tó ń gbé ilé àkọ́kọ́ ti lọ síbi iṣẹ́, èkejì lọ sílé ìwòsàn, nígbà tí ẹ̀kẹta lọ rajà. Tọkọtaya náà wá ẹni àkọ́kọ́ lọ sílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Wọ́n bá ẹnì kejì pàdé níbi tí wọ́n pàtẹ ìwé wa sí nítòsí ilé ìwòsàn. Wọ́n sì pe ẹnì kẹta lórí fóònù.