Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a A lè fi Sátánì wé ọdẹ kan tó gbówọ́ gan-an. Gbogbo ọ̀nà ló ń wá láti dẹkùn mú wa láìka bó ṣe pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Sátánì ṣe ń lo ìgbéraga àti ojúkòkòrò láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àá tún kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn kan tí wọ́n gbéra ga, tí wọ́n sì ṣojúkòkòrò, àá sì rí ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní dà bíi wọn.