Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Torí àìpé wa, a lè ṣe tàbí sọ ohun tó máa dun àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà míì. Kí ló yẹ ká ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Ṣé a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà? Ṣé ó máa ń yá wa lára láti tọrọ àforíjì? Àbí ṣe la máa ń ronú pé tí wọ́n bá bínú wàhálà tiwọn nìyẹn? Ṣé a máa ń tètè bínú torí ohun táwọn èèyàn ṣe tàbí sọ? Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé a máa ń dá ara wa láre, ṣé a sì máa ń sọ pé wọ́n á gbà mí bí mo ṣe rí ni o? Àbí a máa rí i bíi kùdìẹ̀-kudiẹ tó yẹ ká ṣiṣẹ́ lé?